Work Is the Medicine Of Poverty – Ise Ni Oguun Ise
Nursery Rhyme to live by: Isé ni òògùn ìsé – Work is the antidote to poverty
We need to remember and teach our children these poems in this complacent and ‘welfare-program for the people of color’ land.
Isé ni òògùn ìsé – work is the antidote/solution to poverty
Múra sí isé re òréè mi – Maintain your qualitative job, my dear friend
Isé ni a fi í di eni giga —quality work can take you places
Bí a kò bá réni fèyìn tì, —— if we have no god-father,
Bí òle là á rí ——–we appear indolent
Bí a ko réni gbékèlé, – if we have no one to rely on
À tera mó isé eni —– concentrate on your work
Ìyá re lè lówó lówó —–your mother may be wealthy
Bàbá sì lè lésin léèkàn —–your father may have a horse stable
Bí o bá gbójú lé won,—- if that is your sole reliance
O té tán ni mo so fún o, -> Take it from me that you are done for
Ohun tí a kò ba jìyà fún,— Anything that comes to you so easy
Kì í lè tójó —— usually does not last
Ohun tí a bá fara sisé fún,—-whatever you work hard to get
Ní í pé lówó eni -> is what lasts because you will cherish it more
Apá lará, ìgùnpá nìyekan –the arm is a family member, the elbow is a sibling
Bí ayé n fé o lónìí,—- if you are currently everyone’s darling
Bí o bá lówó lówó, ——- only if you are wealthy
Ni won á máa fé o lóla —- will they keep loving you
Tàbí tí o bá wà ní ipò àtàtà, —- or when you are in a high position
Ayé á yé o sí tèrín-tèrín,— all will gravitate towards you in warm embrace
Jé kí o di eni n ráágó,—–wait till there is a down turn
Kí o rí báyé ti í símú sí o —–and see how you will be ridiculed
Èkó sì tún n soni í dògá, —–education also elevates one
Múra kí o kó o dáradára —— get a very qualitative education
Bí o sì rí òpò ènìyàn, ——and if you know people
Tí wón n fi èkó se èrín rín,—-not countenancing education
Dákun má se fara wé won —- please do not emulate such/avoid such
Ìyà n bò fómo tí kò gbón,—-Suffering will confront the simple minded
Ekún n be fómo tó n sá kiri —sorrow awaits the truant
Má fòwúrò seré, òréè mi, — do not waste your early childhood, my friend
Múra sísé, ojó n lo —-maximize your potentials for time waits for no one.